Oṣù kéjì ọdún ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (USA) jẹ́ àsìkò ti wọn máa ṣe ìrántí ìtàn àwọn adúláwọ̀ ti o jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nínú oṣù yìí, ní àwọn ará ilẹ̀ Amẹ́ríkà máa bojúwo ẹ̀hìn láti rántí onírúurú ohun ti o ṣẹlẹ̀ si ènìyàn aláwọ̀-dúdú ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni sáà kan. Iṣe ribiribi ti Martin Lurther King àti àwọn aṣíwájú òmìrán, ṣe láti jà fún ẹ̀tọ́ (àti ìgbélarugẹ ipò) àwọn adúláwọ̀ ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà pẹ̀lú ọ̀nà látí pèsè idọ́gbandọ́gba nípa: - ẹ̀tọ́ fún adúláwọ̀ lati dìbò, - àyípadà àwọn òfin ti o ya ọmọ aláwọ̀-dúdú sọ́tọ̀ ni ilé-ìwé, - ẹyawó láti ra ile, - àti àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ míràn, jẹ́ nkan ìwuri nlá fún gbogbo ènìyàn aláwọ̀-dúdú káàkiri àgbáyé. Nítọrí àṣeyọrí ìjà fún ẹ̀tọ́ àwọn adúláwọ̀ ní ilẹ̀ Amerika, ní àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá fi pọ̀ ka kiri àwọn ìpínlẹ̀ àti ìlú Amerika. Ko si ìlú pàtàkì ní Amerika, ti ẹ ti ní ri ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá, bo jẹ ìlú Atlanta (ní ìpínlẹ̀ Georgia) tàbí ìlú Houston (ní ìpínlẹ̀ Texas) tàbí ìlú nlá New York. Ìtọ́ka sí ìparí – Oṣù fún ìtàn adúláwọ̀ ní Amẹ́ríkà – 02/2012 »
source
|
|
|
Commentaires
Vous pouvez suivre cette conversation en vous abonnant au flux des commentaires de cette note.