Accueil

Ní ayé àtijọ́, Òjò àti Iná jùmọ̀ ń du obìnrin kan láti fi í ṣaya.
Nígbà tí ọjọ ìgbéyàwó pé wọ́n fa ọmọ sí ìta gbañgba.
Wọ́n sì sọ pé ẹni bá ti lágbára jù nínú awọn méjéèjì ni ki ó fi í ṣaya.
Iná ló kọ́kọ́ dé. Ó sì ki ọmọ mọ́lẹ̀, ó ń gbé e lọ.
Òjò sì ti ṣú kẹlẹkẹlẹ.
Ọmọbìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin báyìí pé:
Iná o, ọ̀rara. Aráńta
Iná pupa bẹ́lẹ́jẹ́ Aráńta
Òjò dúdú bọ̀lọ̀jọ̀ Aráńta
Kàkà ñ fẹná ma fójò Aráńta
Òjò lọkọ àgbàdo Aráńta
Òjiijì ni òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀,
Ó pa iná kú pátápátá.
Ó si gbé ọmọbìnrin náá lọ.
source

L'utilisation des commentaires est désactivée pour cette note.
Commentaires